ÀKAYÉ KEJÌ. Ògèdè jé òkan lára àwon ohun ogbin ile wa. Àwon àgbè tó wà ni ile ìgbó ló máa ń gbin ògèdè. Omi se pàtàkí fún dídàgbà ògèdè. A ní oríṣíí…

Source: JAMB · 2024

ÀKAYÉ KEJÌ.
Ògèdè jé òkan lára àwon ohun ogbin ile wa. Àwon àgbè tó wà ni ile ìgbó ló máa ń gbin ògèdè. Omi se pàtàkí fún dídàgbà ògèdè.
A ní oríṣíí ògèdè méjì. Ekinni ni èyí tí an pè ní ògèdè agbagba. Irú ògèdè yìí máa ń tobí dáadáa, Oríṣìí keji ni ògèdè where. Eyí lè jé pàrántà tàbí òmíìnì. Igi to n so ògèdè yálà párantá tàbí àgbagbà kò dabí oríṣíí igi yòókù. Ó rorun láti fi ádá gé nítoṛi pé igi rè rò.
Nígbà tí ògèdè bá dàgbà tí èso rè sì ti gbó, a máa sá a. Ògèdè mìíran á ti so ní ìdí èyí tí a sá omo lórí rè, a ó wa gé igi rè lule. Ìdí níyìí tí a fi ń pòwe pé, “bí iná bá kú á féérú bojú, bí ògèdè kú a fomo rè rópò.” Igi ògèdè tí ó so ní ìdí rè yìí ni yóò dípò èyí tí a gé lule. Ìgbà èerùn ni ògèdè máa ń pò lója. Ògèdè weerè ni a fi máa ń panu tí ó bá ti pón. Ìwúlò ògèdè àgbagbà pò púpo. A lè fi dúdú rè se èlùbó, a lè sè é mó ìsú láti gún ìyán je, a tún lè fí se àṣáró tàbí kí a fi din ìpékeré. Bí ògèdè àgbagbà bá pón, a lè jẹ é ní túútù tàbí kí a sè é jẹ. Ti a bá fẹ́, a lè sè é mo èwà tàbí kí a din in ní dódò. Àwon miiran a si máa fi pon otí agadangidi. Dáhun àwọn ìbéèrè wònyi.Ògèdè ni a fi n se àwọn oúnje wọnyì àyàfì

  1. ewedu ✓
  2. èlùbo
  3. dòdò
  4. ìpékeré
Explanation

The passage names foods made from plantain: èlùbọ́ (plantain flour), àṣáró (porridge), ìpékeré (plantain chips) and dòdò (fried plantain).

Ewédú is a soup made from jute leaves. It is not made from plantain, so it is the answer.

Was this explanation helpful?

Something wrong or missing? Tell us — we read every report and fix issues fast.