ÀKAYÉ KEJÌ. Ògèdè jé òkan lára àwon ohun ogbin ile wa. Àwon àgbè tó wà ni ile ìgbó ló máa ń gbin ògèdè. Omi se pàtàkí fún dídàgbà ògèdè. A ní oríṣíí…

ÀKAYÉ KEJÌ.
Ògèdè jé òkan lára àwon ohun ogbin ile wa. Àwon àgbè tó wà ni ile ìgbó ló máa ń gbin ògèdè. Omi se pàtàkí fún dídàgbà ògèdè.
A ní oríṣíí ògèdè méjì. Ekinni ni èyí tí an pè ní ògèdè agbagba. Irú ògèdè yìí máa ń tobí dáadáa, Oríṣìí keji ni ògèdè where. Eyí lè jé pàrántà tàbí òmíìnì. Igi to n so ògèdè yálà párantá tàbí àgbagbà kò dabí oríṣíí igi yòókù. Ó rorun láti fi ádá gé nítoṛi pé igi rè rò.
Nígbà tí ògèdè bá dàgbà tí èso rè sì ti gbó, a máa sá a. Ògèdè mìíran á ti so ní ìdí èyí tí a sá omo lórí rè, a ó wa gé igi rè lule. Ìdí níyìí tí a fi ń pòwe pé, “bí iná bá kú á féérú bojú, bí ògèdè kú a fomo rè rópò.” Igi ògèdè tí ó so ní ìdí rè yìí ni yóò dípò èyí tí a gé lule. Ìgbà èerùn ni ògèdè máa ń pò lója. Ògèdè weerè ni a fi máa ń panu tí ó bá ti pón. Ìwúlò ògèdè àgbagbà pò púpo. A lè fi dúdú rè se èlùbó, a lè sè é mó ìsú láti gún ìyán je, a tún lè fí se àṣáró tàbí kí a fi din ìpékeré. Bí ògèdè àgbagbà bá pón, a lè jẹ é ní túútù tàbí kí a sè é jẹ. Ti a bá fẹ́, a lè sè é mo èwà tàbí kí a din in ní dódò. Àwon miiran a si máa fi pon otí agadangidi. Dáhun àwọn ìbéèrè wònyi.Ìgbà …… ni ògèdè máa ń pò ní ojà.

  1. eerun ✓
  2. òjò
  3. òtútù
  4. oginnitin

Explanation

The passage directly states that dry season (eerun) is when plantains are abundant in the market. This is the season when they are harvested most.

Farmers harvest more plantains during dry season. The weather conditions make the fruit ripen well. Markets get full of plantains at this time.

Knowing harvest seasons helps you understand agricultural cycles. Different crops have different best seasons.